Skip to main content

Posts

Showing posts with the label LINGUISTICS AND YORUBA

ÀGBÉỲẹWÒ ÀWọN FÍÌMÙ ÀGBÉLÉWÒ MÚYÌWÁ ADÉMỌ́LÁ TÍ ILÉ-IṣẸ́

ÌPÌLẸ̀ IṢẸ́ 1.0    Ìfáárà     Fíìmù jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwợn iṣẹ́-ọnà tí à ń lò láti fi àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ni kò mọ àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ àmì ìdánimọ̀ wọn nù. Àkíyèsí fi hàn pé, ọ̀pọ̀ òṣèré ni wọ́n máa ń ṣe ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá nínú fíìmù wọn. A lérò pé èyí yóò fún àwọn tí kò mọ àṣà àti ìṣe Yorùbá ní àǹfààní láti mọ àwọn àṣà àti ìṣe náà. Èyí ni ó mú kí a dágbá lé iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ fíìmù léte àti ṣe àfihàn àwọn àṣà àti ìṣe Yorùba.     Adágbádá (2005) pe fíìmù ní àwòrán tí a ká sínú àgbá, tí a fi ẹ̀ro àti iná mọ̀nàmọ́ná gbé àwòrán rẹ̀ lọ sára ògiri fún òǹwòran láti wò ni sinimá.     Adágbádá (2008) tún pe fíìmù ní àkànṣe àwòrán tí a fi ẹ̀rọ gbà sílẹ̀ lóko eré tí a ṣe sínú fọ́nrán onírúurú fún ìgbádùn àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́.     Gẹ́gẹ́ bí oríkì méjì yìí, A lè pe fíìmù ní eré tí a máa ń wò nínú ilé tó sì jẹ́ pé àwa ni a ni ẹ̀rọ ìwòran tí a fi ń wò ó ...