ÌPÌLẸ̀ IṢẸ́
1.0 Ìfáárà
Fíìmù jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwợn iṣẹ́-ọnà tí à ń lò láti fi àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ni kò mọ àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ àmì ìdánimọ̀ wọn nù. Àkíyèsí fi hàn pé, ọ̀pọ̀ òṣèré ni wọ́n máa ń ṣe ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá nínú fíìmù wọn. A lérò pé èyí yóò fún àwọn tí kò mọ àṣà àti ìṣe Yorùbá ní àǹfààní láti mọ àwọn àṣà àti ìṣe náà. Èyí ni ó mú kí a dágbá lé iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ fíìmù léte àti ṣe àfihàn àwọn àṣà àti ìṣe Yorùba.
Adágbádá (2005) pe fíìmù ní àwòrán tí a ká sínú àgbá, tí a fi ẹ̀ro àti iná mọ̀nàmọ́ná gbé àwòrán rẹ̀ lọ sára ògiri fún òǹwòran láti wò ni sinimá.
Adágbádá (2008) tún pe fíìmù ní àkànṣe àwòrán tí a fi ẹ̀rọ gbà sílẹ̀ lóko eré tí a ṣe sínú fọ́nrán onírúurú fún ìgbádùn àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́.
Gẹ́gẹ́ bí oríkì méjì yìí, A lè pe fíìmù ní eré tí a máa ń wò nínú ilé tó sì jẹ́ pé àwa ni a ni ẹ̀rọ ìwòran tí a fi ń wò ó bẹ́ẹ̀ ni ó sì lè jẹ́ eré tí a lọ fi owó wò ní gbọ̀ngàn eré.
Fíìmù jẹ́ ẹ̀ka lítíréṣ̀ọ tí ó ní àwọn àbùdá àdámọ́ eré oníṣe tí ó jẹ́ ẹ̀ka kan nínú ẹ̀ka mẹ́ta tí lítíréṣọ̀ pín sí. Lára àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀ ni: Ibùdó- Ìtàn, Ìkóniláyà sókè, Ìjọnilójú, Ẹ̀dá-Ìtàn-ajẹ-méré- oníṣe, Kókó-Ọ̀rọ̀, Ìtàkùrọ̀sọ láàárín àwọn òṣèré àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lítíréṣọ̀ máa ń dánilẹ́kọ̀ọ́, ó sì tún máa ń dánilárayá bákan náà ni fíìmù wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilárayá.
Oríṣiríṣi àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni àwọn òṣèré máa ń fihàn nínú fíìmù yálà láti ṣe ìgbélárugẹ àwọn àṣà àti ìgbàgbọ́ náà tàbí láti ṣàfihàn àwọn àyípadà tó ti dé bá wọn nípa ẹ̀sìn, ọ̀làjú àti àwọn nǹkan mìíràn. Èyí ni yóò mú kí á wo bí Múyìwá Adémọ́lá àti Adébáyọ̀ Tìjání ṣe ṣàfihàn ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Orí-Inú nínú àwọn fíìmù àgbéléwò wọn.
Ní orí kìíní àpilẹ̀kọ yìí ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa èrèdí iṣẹ́ yìí, ọgbọ́n ìwádìí fún iṣẹ́ yìí, ibi tí iṣẹ́ yóò fẹjú dé, ìṣòro iṣẹ́ yìí, tíọ́rì ìṣàmúlò, a ó ṣàgbéyẹ̀wò àwọn tó ti ṣiṣẹ́ lórí fíìmù Yorùbá àti àfihàn ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa orí-inú.
1.1 Èrèdí Iṣẹ́ Yìí
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí kò bá nídìí, Obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú, Èrèdí pàtàkì tí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí fi wáyé ni láti ní ìmọ̀ kíkún nípa ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Orí-Inú àti pé gbogbo ọgbọ́n àti ète àwọn òṣèré láti ṣàfihàn ìgbàgbọ́ Yorùbá yìí nínú àwọn fíìmù wọn jẹ́ ohun tó mú wa lọ́kàn. Ìdí nìyí tí a fi fẹ́ gbìyànjú láti fi wọ́n hàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan léte àti fa àwọn iṣẹ́ tí wọ́n fi wọ́n rán sí àwùjọ yọ.
1.2 Ọgbọ́n Ìwádìí
Ọgbọ́n ìwádìí ni a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí oríṣiríṣi ìgbésẹ̀ tí olùwádìí gbé tàbí gbogbo ọ̀nà tí ó gbà láti lè jẹ́ kí iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ ṣe é ṣe. Ọ̀pọ̀ ọgbọ́n ìwádìí ni a ṣe àmúlò wọn nínú iṣẹ́ yìí lára wọn ni: wíwo fíìmù Ògo Òṣùpá, Orí, Ajá, Gbáyépẹ́ àti Ìpín tí Múyìwá àti Tìjání lò láti fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa orí-inú hàn. A kà nípa tíọ́rì ìbára-ẹni-gbépọ̀ àti lámèétọ́ àṣà, a wo ìtàn ìgbésí-ayé àwọn olùkọ̀tàn. Bákan náà, ni a lọ sí yàrá ìkàwé láti ka àwọn ìwé tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwádìí náà. A tún ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àtẹ̀yìnwá lórí ìtúpalẹ̀ fíìmù.
1.3 Ibi Tí Iṣẹ́ Yóò Fẹjú Dé
Nínú iṣẹ́ yìí, a fẹ́ ṣe àgbéỳẹwò àwọn fíìmù àgbéléwò Múyìwá Adémọ́lá tí ilé-iṣẹ́ “Muy authentic films and production ” gbé jáde. Àwọn fíìmù náà ni: Ògo Òṣùpá (2003), Orí (2004) àti ti Adébáyọ̀ Tìjání tí ilé-iṣẹ́ “Àsùmọ́ films international limited” gbé jáde. Àwọn fíìmù náà ni: Ajá (2015), Gbáyépẹ́ (2016), Ìpín (2016).
A ó sọ ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀tàn Múyìwá Adémọ́lá àti Adébáyọ̀ Tìjání, a ó tún sọ àwọn ìtàn fíìmù náà ní ṣókí ṣókí, a ó ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa orí-inú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú iṣẹ́ yìí, A ó sọ èrò tiwa nípa orí-inú, A ó sọ àrokò tí àwọn òǹkọ̀tàn fi àwọn fíìmu wọn pa ránṣẹ́ sí àwùjọ. A ó tún sọ ipa tí àwọn fíìmù ajẹmọ́ orí-inú ń kó láwùjọ yorùbá. Lákòótán, a ó sọ àwọn àríwísí tí ó wà lórí àwọn fíìmù tí Múyìwá Adémọ́lá àti Adébáyọ̀ Tìjání tí a lò làti fi ìgbàgbọ́ yorùbá nípa orí-inú hàn bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ṣàì sọ nípa àwọn àléébù tí a ṣe àkíyèsí pé àwọn fíìmù náà ní.
1.4 Ìṣòro Iṣẹ́ Yìí
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní onísùúrù ní í fún wàrà kìnìún àti pé títa ríro là á kọ ilà, tó bá jinná tán a doge. Àwọn òwe wọ̀nyí kò ṣàìṣẹ mọ́ wa lára nígbà tí à ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro ni a kojú nínú iṣẹ́ yìí. Àkọ́kọ́ ni ìṣòro làti rí àwọn ìwé tí ó ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Ó gba ọ̀pọ̀ àkókò, owó, àti ìrìn àjò lóríṣiríṣi ká tó rí ọ̀pọ̀ ìwé tí a ṣàmúlò nínú iṣẹ́ ìwádìí náà. Bákan náà la dojúkọ onírúurú ìṣòro mìíràn láti rí i pé a ṣe iṣẹ́ yìí ní àṣeyọrí.
1.5 Tíọ́rì Àmúlò
Tíọ́rì méjì tí a ó múlò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni: Tíọ́rì ìfojú ìbára-ẹni gbépọ̀ wo lítíréṣọ̀ àti Tíọ́rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wo lítíréṣọ̀ Yorùbá.
1.5.1 Tíọ́rì Ìfojú Ìbára Ẹni-Gbépọ̀ Wò
Ogúnlọ́gọ̀ àwọn onímọ̀ ló ti ṣiṣẹ́ lórí tíọ́rì yíì, Ọ̀pẹ́fèyítìmí (2014: 51, 149-151) tọ́ka sí Duncan (1961), Preminger et al (1974) àti Bámidélé (2000) gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọn ṣiṣẹ́ takuntakun lórí tíọ́rì ìfojú ìbára-ẹni-gbépọ̀ tí a lò yíì. Ẹ jẹ́ kà wo ohun tó ní wọ́n sọ àti àlàyé tó ṣe nípa rẹ̀.
Duncan (1961:59 & 112) sọ pé “this kind of analysis assumes
that the practice of literature … concern with specific
social problems.”
Tó túmọ̀ sí pé;
Irú ìtúpalẹ̀ yìí gb̀a pé iṣẹ́ lítíréṣọ̀…
jẹ mọ́ irúfẹ́ àwọn ìṣòro kan pàtó tó ń dojú kọ àwùjọ.
Duncan tèsíwájú nípa sí sọ́ pé:
A sociologist must do more than stress the persuasive quality of symbolic appeals to audience… must point out specific sociological contexts in the process of identification, as these arise when the self and the other are addressed.
Ìtumọ̀:
Onímọ̀ sosiọ́lọjì lítíréṣọ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ju pé kó pàkíyèsí sí àbùdá ìgbatẹni ti àmì ń ṣe fún olùgbọ́ lọ… ó gbọdọ̀ sọ pàtó ọ̀gangan-ipò ìbára-gbépọ̀ lákòókò tó bá Òǹkọ̀tàn ṣe àfàyọ, nítorí àwọn ǹnkan wọ̀nyí ń wáyé nígbà tí a bá ń bá ara ẹni tàbí ẹlòmíràn wí.
Preminger et al (1974: 168) ṣe èkúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí ìlànà yìí jẹ mọ́. Ìgbàgbọ́ àwọn onímọ̀ yìí ni pé èso àwùjọ ni lítíréṣọ̀ àti pé àwọn nǹkan tó ń mi àwùjọ ló ń ti oníṣẹ́ ọnà àti iṣẹ́ ẹ rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí á fi oríkì Baldick (2004: 238) lórí ìmọ̀ ṣoṣiọ́lọ́́jì lítíréṣọ̀ bẹ̀rẹ̀ báyíì pé:
Sociology of literature, a branch of literary study that examines the relationships between literary works and their social contexts including kinds of audience… dramatic presentation and the social positions of authors and readers.
Tó túmọ̀ sí pé;
ìmọ̀ ṣoṣiọ́lọ́jì lítíréṣọ̀ jẹ́ ẹ̀ka ìm̀ọ lítíréṣọ̀ kan tó ń ṣàgbéyẹ̀wò àjọṣepọ̀ tó wà láàárín iṣẹ́ lítíréṣọ̀ àti ọ̀gangan-ipò wọn láwùjọ, pẹ̀lú… irúfẹ́ olùgbọ́… ìlànà ìṣèré àti ipò òǹkọ̀wé àti òǹkàwé.
Nínú àpèjúwe yìí, a rí i pé ọ̀gangan-ipò (àwùjọ) ṣe pàtàkì fún ṣoṣiọ́lọ́jì lítíréṣọ̀.
Ìdí ni pé ọ̀gangan-ipò, orísun (òǹkọ̀wé tàbí apohùn) àti àbọ̀ (òǹkàwé tàbi olùgbọ́) ló jẹ àwọn onímọ̀ soṣíọ́lọ́jì lítíréṣọ lógún.
Bámidélé (2000:23) rí àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àṣà àti àwùjọ nínú lítíréṣọ̀ tí àwọn tíọ́rì tó kù kò mú lọ́kùn-únkúndùn. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tó sọ gan-an:
Criticism will always have two aspects, one turned towards the structure of literature as a whole and one turned towards the other cultural phenomena that form its environment. Together they balance each other.
ìtumọ́:
iṣẹ́ lámèétọ́ máa ń ní abala méjì, ọ̀kan máa ń wo ìhun lítíréṣọ̀, èkejì sí máa ń wo abala àṣà tó jẹ mọ́ àyíká rẹ̀. Lápapọ̀, wợn á sì ranra wọn lọ́wọ́.
Adébọ̀wálé (2003:1) náà sọ pé:
Ìmọ̀-ìbára-ẹní-gbépọ̀ láwùjọ tẹpẹlẹ mọ́ àṣà, ìṣe, ìgbàgbọ́ àti ìwòréré ayé àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni ó sọ ipa tí àwùjọ ń kó lórí ènìyàn.
Lára àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí tó gbajúmọ̀ ni òpìtàn ará Faransé tí ǹ jẹ “Hippolyte Taine” tó ṣe àgbékalẹ̀ ohun tó pè ní “the race, the milieu, the moment” nípa sẹ̀ tíọ́rì yìí. A le túmọ “race” sí ìran, “milieu” ni ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìwà ní àkókò kan pàtó èyí tí a fi ń ṣòdiwọ̀n ìtàn lítíréṣọ̀. “Moment” ni ohun tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́, èyí tóun náà ní í ṣe pẹlú òdiwọ̀n àkọ́́kọ́. Wọ́n ní àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí ló ń para pọ̀ ran òǹkọ̀wé lọ́wọ́ tó sì ǹ ṣatọ́kùn ìwà iṣẹ́ ẹ wọn.
Ohun tí a rí fàyọ nínú àlàyé àwọn onímọ̀ wọ̀nyí ni pé lẹ́yìn tí a bá ti lo àwọn tíọ́rì láti tú iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀ palẹ̀ tán, a tún gbọdọ̀ wá èyí tí a ó fi tan ìmọ́lẹ̀ si àwùjọ tí lítíréṣọ̀ náà jẹ́ èso fún. Bí a bá sì ń sọ́rọ́ àwùjọ, àwọn ènìyàn, àyíká àti àṣà ṣe pàtàkì. A tilẹ̀ gbàgbọ́ pé àwùjọ ló pile lítíréṣọ̀. Nínú r̀ẹ ni ìṣẹ̀dá ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a fẹ́ túpalẹ̀ ti jáde. Ìdí nìyí tí a fi rò pé ìmọ̀ tó jẹ mọ́ àwùjọ ló yẹ ká kọ́kọ́ tanná rẹ̀ wo àwọn fíìmù tí wợn fi ìgbàgbọ́ Yorúbà hán nípa orí-inú.
1.5.2` Tíọ́rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀ wo lítíréṣọ̀
Tíọ́rì kejì tí a ṣàmúlò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni tíọ́rì ìfojú- àṣà- ìbílẹ̀ wo lítíréṣọ̀ Yorùbá. Ọ̀pẹ́fèyítìmí (2014:61-62) tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Preminger àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ (1993: 262) tí wọn ṣàlàyé pé láti ọ̀rúndún kejìdínlógún ni lámèétọ́ àṣà ti di dídásílẹ̀. Àkíyèsí pàtàkì ni pé àpèjúwe àṣà àti gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ ọn ló jẹ àwọn oní lámèétọ́ àṣà lógún. Ệ jẹ́ ká wo bí díẹ̀ lára àwọn onímọ̀ ti ṣàpèjúwe àwọn ohun tí a lè kà kún àṣà àwùjọ kan.
Oyerinde (1981) rí àṣà gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣesí àwọn ènìyàn kan. Ó lè jẹ́ lára ìwà àjùmọ̀hù bí i oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ, aṣọ tí ń wọ́n wọ̀, iṣẹ́ tí wọn ǹ ṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ilésanmí (1989:2) rí àṣà gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tó jẹ mọ́ àṣà àwọn asùwàdà kan, ohun tí Ilésanmí ń sọ ni pé àṣà lè jẹ́ ti àdúgbò tàbí ẹ̀yà kan. Ó tẹ̀síwájú pé ìṣẹ̀se ló máa ń dúró, àṣà máa ń yípadà láti ìgbàdégbà.
Irélé (1991:52) ṣàlàyé pé nígbà tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àṣà, ohun méjì ni à ń sọ̀rọ̀ nípa rè lọ́nà kín-ín-ní, a ní àwọn àṣà ènìyàn tí a lè rí àpèjúwe rẹ̀ tí a tilẹ̀ lè fọwọ́ kàn lọ́pọ̀ ìgbà, èkejì ni ohun tí ó jẹ́ èrò àti ìgbàgbọ́ ènìyàn. Bí àpẹẹrẹ olódùmárè gẹ́gẹ́ bí Elẹ́dàá wa, a kò lè fọwọ́ kàn àn sùgbọ́n a mọ̀ pé ó wà.
Thompson (1991) pe àṣà ní àkójọpọ̀ ìlànà ìgbé ayé àwùjo kan ní ìbámu pẹlú ìwòye àwùjọ bẹẹ ní àkókò kan ní pàtó. Ó lè jẹ́ ìhùwàsí wọn, ohun èlò wọn, ìrònú wọn, ìmọ̀sílára wọn mọ́ àwọn ohun yòókù tó lè mú kí àwùjọ ṣe é gbé.
Ládélé (2006:10) jẹ́ kí ó yé wa pé kó sí ohun tí Yorùbá le rò tàbí tí wọ́n le ṣé tí kó rọ̀ mọ́ àsà ó ní kò sí èrò tàbí ìṣẹ́ tí kò bá àsà lọ láwùjọ Yorùbá.
Onímọ̀ yìí Ọ̀pẹ́fèyítìmí (2014:62) tún tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Mathew Arnold (1969) tí ó sọ pé;
Culture is the pursuit of a best self and a general perfection, motivated by passion for pure knowledge and for social and moral right, action, affected by reading, observing and contemplating. The voices of human experience in art, science, poetry, philosophy, history and religion.
Ìtúmọ̀
Àṣà ni ìlépa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti lè dára tó bó ti ń fẹ́, nípasẹ̀ ìfẹ́ ìmọ̀ tí ò lábùlà àti fún ṣíṣe ẹ̀tọ́ tó bójúmu láwùjọ, ìṣe èyí tí a lè rí nípasẹ̀ ìkàwé, ìwoṣàkun àti ìgbìyànjú. Oríṣiríṣi ìrírí ẹ̀dá àwùjọ nínú iṣẹ́-ọnà, sáyẹ̀nsì, ewì, èrò-ìjìnlẹ̀, ìtàn àti ẹsìn.
Ọ̀pẹ́fèyítìmí (2014) kò ṣàì tọ́ka sí onímọ̀ kan tí wọ́n ń pè ní Taylor gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fún àṣà ní àpèjúwe tó rinlẹ̀ jù Ó pe àṣà ni:
That complex whole which includes knowledge, belief, art, morals, law, custom and any other capabilities and habits acquired by man as a member of society.
Ìtúmọ̀:
Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan bí ìmọ̀, ìgbàgbọ́, iṣẹ́-ọnà, ìwà ọmọlúàbí, òfin, iṣẹ́ òhun ipa àti ìwà tí ènìyàn jogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀dá ènìyàn àwùjọ kan.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Ọ̀pẹ́fẹ̀yìtìmí, Raymond William gbà pé àṣà kò pin sí àkójọpọ̀ ìlànà iṣẹ́ ìwádìí àti iṣẹ̀ ọpọlọ nìkan, ó tún jẹ́ gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ ìgbésí ayé ẹ̀dá. Ní ìbámu pẹ̀lú sísapá àwùjọ láti ní àṣà tó jẹ́ àjọṣe. William tẹnumọ́ àǹfààní tó wà nínú ìtọ́ka sí àwọn àkíyèsí tí iṣẹ́-ọnà ń tọ́ka sí. Bákan náà ni onímọ̀ yìí (Ọ̀pẹ́fèyítìmí) tún ṣàfihàn àwọn onímọ̀ tó wà ní gbọ̀ǹgàn ìmọ̀ tí wọ́n pè ní “Univeristy of Birmingham’s centre for contemporary culture studies” gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣagbátẹrù tíọ́rì yìí. Tíọ́rì yìí wúlò lọ́pọ̀lọ́pọ̀ fún iṣẹ́ ìwádìí yìí nítorí pé ohun tó jẹ mọ́ àṣà àti ìgbágbọ́ àwùjọ kan ni a fẹ́ ṣe àfihàn rẹ̀.
1.6.1 Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Àtẹ̀yìnwá
Ogúnlọ́gọ̀ àwọn onímọ̀ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ takun takun lórí ìgbéǹde fíìmù ní ilẹ̀ ẹ wa.
Clark (1979) jẹ́ ká m̀ọ pé lẹ́yìn tí àwọn gẹ̀ẹ́sì dé àwùjọ wa ni eré onílànà Ògúnǹdé bẹ̀rẹ̀. Ó ní àwọn ẹrú tí wọ́n gba òmìnira tí wọ́n dé sí Èkó láti ilẹ̀ Sàró, Brazil àti Kúbà ló mú àṣà ìṣèré ti òkè-òkun wọ ìlú Èkó, eré ní èdè gẹ̀ẹ́sì sì ni ó wọ́pọ nígbà náà. Nígbà tí ó di àkókò kan ni Ògúnǹdé pinnu pé kò yẹ kí á máa wo sinimá ní èdè gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí kì í ṣe pé a kò ní èdè abínibí ara wa.
Nígbà tó yá, wọ́n b̀ẹr̀ẹ sí ń ṣe eré oníṣe ní èdè Yorùbá. Ní àkókò yìí ni eré onítàn gbilẹ̀ sacred cantata àti native Air opera ni àwọn eré oníṣe Yorùbá tó kọ́kọ́ gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Clark ṣe sọ. Onímọ̀ yìí pín akitiyan Ògúnǹdé sí ọ̀nà mẹ́ta;
a) Àkókò Oníjólórin
b) Àkókò Kọ́nsáàtì
c) Àkókò Bágbàmu
Àkókò bágbàmu ni Ògúnǹdé b̀ẹr̀ẹ sí wá àḱọlé Yorùbá fún àwọn eré-onítan rẹ.
Ekwuazi H. (1987: 14-16) sọ nínú ìwé e rẹ̀ “films in Nigeria” pé oṣù kẹ́ta ọdún 1903 ni wọ́n kọ́kọ́ wo fíìmù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìlú Èkó lásìkò àwọn òyìnbó amúnisìn. Fíìmù tí àwọn òyìnbó gbé wá tí wọn kọ́kọ́ wò ní The coronation of King Edward the 4th. Lẹ́yìn èyí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ eré ní èdè gẹ̀ẹ́sì tí ó kún fún ìwà, àṣà àti ìṣe àwọn òyìnbó ni ó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ adúláwọ̀.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún títí di ẹ̀yìn àkókò tí a gba òmìnira. Ìgbà yìí ni Ògúnǹdé pinnu pé kò yẹ kí á má a wo sinimá ní èdè gẹ̀ẹ́sì nígbà tí kì í se pé a kò ní èdè abínibí tiwa.
Samuel (1999:7) náà sọ pe kí á tó gba òmìníra, fíìmù àtọhúnrìnwá tí a fi èdè gẹ̀ẹ́sì gbé kalẹ̀ níkan ni ó wà. Ó ní lẹyìn tí Nàìjíríà gba òmìnira ni ṣíṣe fíìmù ní èdè abínibí wa bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ogun ab́ẹlé ilẹ̀ Nàìjíríà. Ní nǹkan bí ọdún 1970 ni ìgbìyànjú àti ṣe fíìmù tiwa-n-tiwa ti bẹ̀rẹ̀. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n kọ́kọ́ fi ṣe fíìmù wọnyí; àpẹẹrẹ wọn ni: son of African, Bisi the daughter of the river ni àwọn eré-oníṣe Yorùbá tó kọ́kọ́ gbilẹ̀ ní àsìkò náà. Ní nǹkan bi ọdún 1976 ni wọ́n gbìyànjú àti máa ṣe fíìmù ní èdè Yorùbá èyí tó ṣàfihàn àṣà àti ìṣe Yorùbá. Àpẹẹrẹ wọ́n ni Taxi Driver, Kádàrá, Ayé, Jáyésinmi, Àròpin ni Tènìyàn, Owó Làgbà, Ogun Ìjàyè, Kànnà Kánná, àti àwọn fíìmù bàbá sàlá bí i Ọ̀rún Móoru àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Adélékè (2005) sọ ọ dí mím̀ọ pé gbàrà tí ilé-iṣẹ́ tẹlifísàn àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ kalẹ̀ sí ìlú Ìbàdàn ní ọdún 1959 ní ̀ọkan-ò-j̀ọkan eré tí ń wáyé lórí tẹlifíṣàn tí àwọn òṣèré bí i, Hubert Ogunde, Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀ ń gbé eré wọn jade lórí ìtàgé. Ekuwazi (1987) àti Ekuwazi (1991) tí ṣiṣẹ rẹpẹtẹ lórí ìbẹrẹ fíìmù ní Nàìjíríà.
1.6.2 Ìdàgbàsókè Fíìmù Ní Ilẹ̀ Nàìjíríà
Ní ọdún 1975 ni fíìmù tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Amadi jáde, èdè Ìgbò ni wọ́n fi ṣe fíìmù náà, ó sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láàárín àwọn Ìgbò lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìpèníjà ni èyí jẹ́ fún àwọn oníṣẹ́ fíìmù tí ó sì mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbé fíìmù jáde ní èdè yòókù ní Naìjíríà.
́Ní ọdún 1976 ní Ọ̀gbẹ́ni Ọlá Balógun gbé fíìmù Àjàní Ògún jáde p̀ẹlú ìrànlọ́wọ́ àwọn àgbà òṣèré méjì ìyẹn Dúró Ládípọ̀ (Ṣàǹgó) àti Adéyẹmí Afọláyan (Ade love). Fíìmù yìí ní fíìmù àkọ́kọ́ ní èdè Yorùbá. Fìímù àkọ́kọ́ lédè Haúsá náà jáde ní ọdún 1977, àkọlé rẹ̀ ni Sheu Umar gẹ́gẹ́ bí Ekwuazi (1987) ṣe sọ.
Mgbejume (1989) àti Okome (1995: 43) ṣiṣẹ́ lórí ìdàgbàsókè fíìmù ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Wọ́n ní Òkè-Òkun ni fíìmù ti wá ní ayé àwọn òyìnbó amúnisìn. Àjàní Ògún ni fíìmù Yorùbá àkọ́kọ́ tí ó jáde ní ọdún 1976. wọ́n ṣe àwọn fíìmù wọ̀nyí sínú fọ́nrán fún gbígbé jáde lórí rédíò, tẹlifísàn, sinimá àti àwo rẹ́kọ́ọ̀dù.
Ní àsìkò yìí, oríṣíríṣi aáyan ni Moses Ọláìyá, Jímọ̀h Àlíù àti Ọlá Ọmọnìtàn ṣe agbátẹ̀rù rẹ̀ nígbà nàá ní WNTV (Western Nigeria Television) tó jẹ́ ilé-Iṣẹ́ tẹlifísàn àkọ́kọ́ ní Áfríkà tí Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ dá sílẹ̀ sí ìlú Ìbàdàn ní ọdún (1959).
Lẹ́yìn àwọn akitiyan ìṣàájú lórí fíìmù ṣíṣe, onírúurú ènìyàn àti ẹgbẹ́ ni ó ń kóra jọ pọ̀ láti dá ilé-iṣẹ́ tí yóò má a gbé fíìmù jade sílẹ̀. Nígbà tí àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ onífíìmù Nàìjíríà gún régé, wọ́n dá ẹgbẹ́ “Nollywood” sílẹ̀ ní ọdún 1965, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ èdè Nàìjíríà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta; Yorùbá, Haúsá, àti Ìgbò papọ̀ mọ́ èdè àyálò Nàìjíríà tí í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì (Kazeem, 2015:8).
Àlàmú (1990:72) pín fíìmù Yorùbá sí ọ̀nà mẹ́rin yìí
A. Fíìmù adálórí àlọ́
B. Fíìmù adálórí ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi
D.Fíìmù ajẹmógun
E. Fíìmù apanilẹ́rin
Lára àwọn fíìmù tó jáde láàárín ọdún 1976 sí 1986 ló wà nínú àtẹ yìí
Àtẹ 1
Àkòrí Fíìmù Olùgbéjáde Èdè Odún
1 Àjàní ògún Ọlá Balógun Yorùbá 1976
2 Ìjà Òmìnira Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1977
3 Ayé Hubert Ògundé Yorùbá 1979
4 Kádàrá Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1979
5 Jáyésinmi Hubert Ògundé Yorùbá 1980
6 Ẹfúnṣetán Aníwúrà Ìṣọ̀lá Ògúnṣọlá Yorùbá 1982
7 Ọ̀run Móoru Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀ Yorùbá 1982
8 Àròpin ni Tènìyàn Hubert Ògundé Yorùbá 1982
9 Ìjà Orogún Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1982
10 Owó Làgbà Ọlá Balógun Yorùbá 1982
11 Ìrèké Oníbùdó Báyọ̀ Adéróhunmú Yorùbá 1982
12 Taxi Driver 1 Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1983
13 Aníkúrá Ayọ̀ Razaki Yorùbá 1983
14 Ààrẹ Àgbáyé Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀ Yorùbá 1983
15 Ìyánu Wúrà Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1985
16 Ogun Àjàyè Àdébáyọ̀ Sàlámì Yorùbá 1986
17 Kanna Kánná Báyọ̀ Adéróhunmú Yorùbá 1986
18 Lísàbí Agbòngbò Àkàlà Ọlátóyè Àìná Yorùbá 1986
19 Ojú Oró Omílánì Moses Yorùbá 1986
20 Ogun Ìdílé Eddie Igbomah Yorùbá 1986
21 Taxi Driver II Àdéyẹmí Afọláyan Yorùbá 1986
22 Apálará Eddie Igbomah Yorùbá 1986
23 Moṣebọ́látán Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀ Yorùbá 1986
Ekwuazi (1987:16-17), Àlàmú (1990:113-114) àti Balógun F. (1987).
Eré ṣíṣe sínú fọ́rán fídíò jẹ́ ọ̀kan lára ìdàgbàsókè tó dé bá fíìmù ṣíṣe ní àwùjọ Yorùbá. Ní ọdún 1985 ni a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Muyideen Àlàdé Àròmirẹ̀ sì ni ̣ẹni àkọ́kọ́ tó ká erè rẹ̀ sínú fọ́nrán fídíò tó pè ní Ẹkùn. Eré yìí ni ó ti kọ́kọ́ gbé jade gẹ́gẹ́ bí sinimá ní ọdún 1980.
Ọ̀gbẹ́ni Àlàdé sọ èyí di mímọ̀ ní oṣù kínní ọdún 2006 ní ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣàn Yọ̀tọ̀mì tí Ọ̀gbẹ́ni Rótìmí Abẹ̀rùàgbà jẹ́ olóòtu rẹ̀. Eléyìí mú kí àwọn eré nàá súnmọ́ àwọn ènìyàn si ju ìgbà tó jẹ́ pé ṣe ni wọn ó lọ si ilé sinimá láti lọ fi owó wo irú fíìmù bẹ́ẹ̀.
Adélékè (2005) sọ pé Ilé-iṣẹ́ “NEK VIDEO” ni ó kọ́kọ́ mú ìmọ̀ràn títa fíìmù àgbéléwò Yorùbá jáde, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn òṣèré bì i Ìṣọ̀lá Ògúnṣọlá, Fatai Oòduà, Charles Olúmọ àti Àlàdé Arómirẹ́ ni àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá fi di ohun tí a ń rí rà lórí àtẹ tí a sì ń wò nínú ilé ara wa lónìí.
Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn fìímù tó jáde ní ọdún 1992 sí ọdún 1997
Àtẹ 2: Àwọn fìímù tó jáde ní ọdún 1992 sí ọdún 1997
Àkòrí Fíìmù Iléeṣẹ́ tó gbe jade Ọdún Èdè
1 Ọkọ yoyo Wẹ̀mímọ́ film & Corporate promotion 1992 Yorùbá
2 Àtẹnujẹ Ọláìyá films & company 1992 Yorùbá
3 Ìtara Ẹ̀dá Ọláìyá films & company 1992 Yorùbá
4 Express ladies Wẹ̀mímọ́ film& corporate promotion 1993 Yorùbá
5 Èèwọ̀ Báyọ̀wá films Int& Gbéngá Adéwùsì 1993 Yorùbá
6 Ìwọ ni Báyọ̀wá films Int& Gbéngá Adéwùsì 1993 Yorùbá
7 Ìdí Ọ̀rọ̀ Adé love films 1993 Yorùbá
8 Òkété Ọláìyá films & company 1993 Yorùbá
9 Pàkúté Ọláìyá films & company 1993 Yorùbá
10 Agbẹ́gilére Ọláìyá films & company 1993 Yorùbá
11 Ọ̀rẹ́ Ọláìyá films & company 1993 Yorùbá
12 Ẹwà Jimoh Àlíù films and company 1994 Yorùbá
13 Ẹlẹ́ṣẹ̀ Ọláìyá films & company 1994 Yorùbá
14 Ọlà Ọlọ́run Ọláìyá films & company 1994 Yorùbá
15 Olùgbẹ́kẹ̀lé Ọláìyá films & company 1994 Yorùbá
16 Ẹsẹ̀ Àárọ̀ Ọláìyá films & company 1994 Yorùbá
17 Orí Ire Arómirẹ́ Video 1994 Yorùbá
18 Ìyá ni wúrà Ade Love films 1994 Yorùbá
19 Ìtùnù Báyọ̀wá films Int& Gbéngá Adéwùsì 1995 Yorùbá
20 Ìrù Ẹṣin Ọláìyá films & company 1995 Yorùbá
21 Ète kéte Jimoh Àlíù films and company 1996 Yorùbá
22 Èbúté I &II Ọláìyá films & company 1996 Yorùbá
23 Ẹ̀dẹ Ọláìyá films & company 1997 Yorùbá
Balógun F. (1987).
Kazeem (2015: 8-10) tọ́ka sí ìdásílẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ onífíìmù Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè tó dé bá fíìmù ṣíṣe ní ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn ẹgbẹ́ tó tọ́ka sí nìwọ̀nyí: “Association of Nigeria Theatre Practitioner (ANTP)” tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1990, “Yorùbá Films Videos Production and Marketer Association of Nigeria (YOFVPMAN)” tí wọ́n dá ní ọdún 2003 àti àwọn ẹgbẹ́ tí àwọn òṣèré kan tún dá silẹ̀ tí àwọn ènìyàn lè má a darapọ̀ mọ́ làti kọ́ nípa eré ṣíṣe. Àwọn ẹgbẹ́ bí i “Coded smile productions” tí Kenny Láńre dá sílẹ̀, “Scene One School of Drama” tí Fúnkẹ́ Akíndélé dá sílẹ̀, “Lagos School of Drama” tí Adébáyọ̀ Sàlámì dá silẹ̀, Kúnlé Afod pe tirẹ̀ ni “Legacy Caucus of Performing Artistes” nígbà tí Fẹ́mi Adébáyọ̀ sọ orúkọ tirẹ̀ ní “Global Fame World” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwádìí tí a ṣe lórí àtẹ àti ẹ̀rọ alátagba káyélújara fi han pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù àgbéléwò Yorùbá ló ti wà lórí àtẹ lónìí. Lára àwọn fìímù aládùn àwòtúnwò náà ló wà nínú àtẹ ìsàlẹ̀ yìí.
Àtẹ 3
Àkòrí Fíìmù Ilé-iṣẹ́ tó gbé e jade Ọdún Èdè
1 Adérónkẹ́ Muy Authentic Films production 1998 Yorùbá
2 Sàngó Ajílẹ́yẹ Films production 1999 Yorùbá
3 Akínkanjú Muy Authentic Films production 1999 Yorùbá
4 Ìjà Ọmọdé Kóredé Films and Production 2000 Yorùbá
5 Òrìṣà Òkè Muy Authentic Films production 2000 Yorùbá
6 Kílọmọdé mọ̀ Kóredé Films and Production 2001 Yorùbá
7 Ìyọ́nú Ọlọ́run Muy Authentic Films production 2002 Yorùbá
8 Ògo Òsùpá Muy Authentic Films production 2003 Yorùbá
9 Àbẹ́là Pupa Ọláìyá films & company 2003 Yorùbá
10 Orí Muy Authentic Films production 2004 Yorùbá
11 Adániwáyé Murphy Afọlábí films Production 2004 Yorùbá
12 Ilẹ̀ Muy Authentic Films production 2005 Yorùbá
13 Jídé Jamal (JJ) Muy Authentic Films production 2006 Yorùbá
14 Tàkúté Ọlọ́dẹ Yínká Quadri films productions 2006 Yorùbá
15 Àpésìn Adékọ́lá Tìjání films production 2007 Yorùbá
16 Bólóde Òkú 1&11 Corporate pictures films production 2008 Yorùbá
17 Alẹ́ Ariwo Wẹ̀mímọ́ film& corporate promotion 2008 Yorùbá
18 Jẹ́nífà Scene one productions 2009 Yorùbá
19 Arẹwà òru Corporate pictures films production 2009 Yorùbá
20 Ọ̀run n’yabà Sir White films & productions 2010 Yorùbá
21 Omi Kàǹga Prime Picture Limited 2011 Yorùbá
22 Ọ̀nà Àbáyọ Komaa Roll Multimedia Limited 2012 Yorùbá
23 Wèrè dùn wò Royal Films Nigeria Limted 2013 Yorùbá
24 Àgídìgbo Tolujab Films Production limited 2013 Yorùbá
25 Agbájé Toymax Films Holding 2014 Yorùbá
26 Ìfẹ́ Ọkàn Gemini Films Limited 2014 Yorùbá
27 Awùsá Babatech films Enterprise 2015 Yorùbá
28 Ọpón ti sún Jim-T world of entertainment 2016 Yorùbá
29 Bẹ́ẹ̀kọ́ Toymax Films Holding 2017 Yorùbá
30 Igbó Dúdú Bánkẹ́ Films Production Limited 2017 Yorùbá
Púpọ̀ nínú àwọn fíìmù wọ̀nyí ló ti wà nínú dísìkì báyìí gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí Olúmúyìwá (2017) tí ó ṣe nígbà tí ó ṣàlàyé pé kì í ṣe orí fọ́nrán fídíò nìkan ni a ti lè rí fíìmù àgbéléwò mọ́ lónìí, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe fíìmù sórí fónrán pẹlẹbẹ kan tí a mọ̀ sí dísíkì irú èyí tí a gba àwọn fíìmù tí a lò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí sí.
1.6.3 Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Tó ti Wà Nílẹ̀ Lórí Ìtúpalẹ̀ Fíìmù
Àkíyèsí tí a ṣe ni pé bí àwọn fíímù wọ̀nyí ṣe ǹ jáde ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ǹ ṣe ìtúpalẹ̀ wọn nípa wíwo kókó-ọ̀rọ̀, àhunpọ̀-ìtàn, ìfiwàwẹ̀dá, Ibùdó-ìtàn, Àṣà àti Ìlò-èdè àwọn òǹkọ̀tàn bẹ́ẹ̀.
Akérédolú (2002) ṣe ìtúpalẹ̀ fíìmù Àbẹ́là Pupa nípa wíwo kókó-ọ̀rọ̀, àhunpọ̀-ìtàn, ìfìwàwẹ̀dá, ibùdó-ìtàn àti ìlò-èdè fíìmù náà ó sì fí hàn pé fíìmù yìí jẹ́ ọgbọ́n àtinúdá to jẹ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ awùjọ tàbí ítán báyému.
Onítọlọ̀ (2006) ṣe ìtúpalẹ̀ fíìmú Ṣawo Ṣọ̀gbèrì. Ó ṣàlàyé pé fíìmù yíì n bá àwọn ahùwà ìbàjẹ́ làwùjọ wí, ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìṣ̀ẹlẹ̀ ojú-ayé ni fíìmú náà jẹ´ àti pé fíìmú yìí jẹ́ ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá.
Ọmọ́dára (2012) ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn fíìmú Alfa Súlè tí Ìlé iṣẹ´ “Christ chosen vessel Dance Drama Ministry” gbé jáde. Àbájáde ìwádìí rè ni pé, lóde-òní Ọ︡pọ̀lọpọ̀ eré-oníṣe ni ó wà láwùjọ Yorùbá tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn fi gbàgbé irúfẹ́ eré oníṣé–oníjó ìyẹn (dance drama). Ọ̀mọ́dárà ní ká gbé áṣà wa lárugẹ nítorí eré oníjó tí ó jẹ́ ohun tó ti wà tipẹ́ ti ń di ohun ìgbàgbé láwùjọ Yorùbá lóde òní.
Fíìmù Yorùbá míìràn tí wọ́n tún ṣe ìtúpalẹ̀ rẹ̀ ni BABÁTÚNDÉ ÌȘỌ̀LÁ FỌ́LỌ́RUNȘỌ́ èyí tí Ọláyinká (2015) ṣe. Iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ fi yé wa pé ní òtítọ́ ni àwọn agbára òògùn wà láyé ṣugbọ́n agbára yìí kò jú agbára Ọlọ́run lọ.
Bí àwọn tó tí ṣiṣẹ́ lòrí fíìmù Yorùbá tí pọ̀ tó, kò sí ẹnikànkan tí a mọ̀ tó ti ṣiṣẹ́ lòrí “Àfihàn Ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Orí-Inú nínú àwọn fiìmù Múyìwá Adémọ́lá àti Adébáyọ̀ Tìjání”.
1.6.4 Ìran Yorùbá
Yorùbá jẹ́ àti- ìran-díran Odùduà p̀ẹlú gbogbo àwọn tí wọ́n ń sìn Ọlọ́run ni ̀ọnà tí Odùdùa gbà sìn-ín, tí wọ́n sì bá a jáde kúrò ní agbedegbede ìwọ̀ oòrùn nígbà tí ìrúkèrúdò dé nípa ìgbàgbọ́ r̀ẹ yìí. Yorùbá ni ọmọ tí a gbà pé a bí ní ilé ọgbọ́n tí a sì wò ó ní ilé ìmọ̀ràn, bí irú ọmọ bayìí yóò ti gbọ́n bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mọ̀ ìmòràn. Yorùbá ní àwọn tí wọ́n gba Odùdùa gẹ́gẹ́ bí baba ǹlá wọn tí wọ́n si gba Ilé-Ifẹ̀ bí orírun wọn. Lára Ilẹ̀ Yorùbá ní Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀ṣà, Àkókó, Èkìtì, Ọ̀wọ̀, Oǹdó, Ìgbómìnà, Ọ̀fà, Ẹ̀gbá, Ẹ̀gbádò, Ìj̀ẹbú, Ìlàjẹ, Ìkálẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Adéoyè 2014: 1-5)
1.6.5 Ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Orí-inú
Ọládipúpọ̀ (2013:13) ki orí-inú báyìí pé
“destiny is conceived as what happens to somebody or what will happen to them in the future especially things that they cannot change or avoid”
Ìtúmọ̀
Orí-inú ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn sẹ́yìn tàbí èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú pàápàá jù lọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lè yí padà.
Dáramọ́lá àti Jéjé (1975: 250-251) tọ́ka sí Ọ̀runmìlà tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀run-mọ-oolà tàbí ọ̀run-mọ-ẹnití-ò-máa la (ìfá) gẹ́gẹ́ bí “Ẹlẹrìí Ìpín” (orí-inú). Ó sọ pe, ó wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọrun dá gbogbo ohun tí ó wà nínú ayè pàápàá jù lọ ènìyàn. Ó mọ gbogbo nǹkan àti pé òun ni Olódùmarè rán sí àwọn Yorùbá làti fi ohun tí ó wà níwájú wọn hàn wọ́n.
Ọ̀pọ̀ onímọ̀ ló ti ṣiṣẹ́ lórí ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa orí-inú tí a mọ̀ sí Ìpín, Àyàmọ́, Kádàrá tabí Àkúnlẹ̀yàn ẹ̀dá.
Adéoyè (1982:4-20) sọ bí Ẹlẹ́dàá ṣe gba àwọn ọmọ abirunlórí atí oríṣiríṣi ẹranko láàyè láti wá dá àníyàn tí ó wù wọn sínú ayé. Olódùmarè fẹ́ kí àkúnlẹ̀yàn gbogbo ẹ̀dá jẹ́ àdáyébá a wọn, kí ó má ba à sí pé ẹnikọ̀ọ̀kan yóò máa ronú pé ẹnìkejì ló ń ṣe é.
Ó ṣàlàyé síwájú si pé, Àkúnlẹ̀yàn oníkálùkù ni àdáyébá a rẹ̀, Àwọn ẹlòmíràn kúnlẹ̀ wọ́n yan ẹ̀dá, wọ́n dáyé tán ojú yán wọn. Ẹ̀dá lọmọ oòdùa, ìṣẹbọ, ìṣògùn bí a tí wáyé rí là á rí, bí olúkálùkù sì tí kúnlẹ̀ tí wọ́n yan ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ni elẹẹ́ẹ̀da fi àrísíkí si fún olúkálùkù wọn.
Adeoye (1989:63) tún ṣàlàyé pé Yorùbá gbàgbọ́ pé lọ́jọ́ tí a bá tí dá àṣẹ ọmọ tuntun ni yóò ti yan orí èyí ni “Orí-inú”. Orí-inú yìí fúnra ọmọ tí a dá àṣẹ rẹ̀ níí yàn án, gbogbo ohun tí yóò bá sì dà ni ilé ayé ni Yorùbá gbàgbọ́ pé a ti kọ mọ́ orí-inú tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí.
O tẹ̀síwájú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ni ìgbàgbọ́ Yorùbá, síbẹ̀ àṣà àti ìgbàgbọ́ wọ́n tún ni pé bí orí bá burú tí ènìyàn kò bá dákẹ́ tí ó bá ṣe aájò lọ́dọ̀ àwọn irúmọlẹ̀, búburú tí orí yàn yóò dínkù. Èyí ní ó fà á tí àwọn Yorùbá fi gbà pé aájo, ẹbọ rírú àti àìdúró lọ́wọ́ lè ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ire fún ẹ̀dá.
Onímọ̀ yìí sọ́ pé lára àwọn òwe tó fi ìgbàgbọ́ wọn hàn lórí iṣẹ́ tí aájò, àdúrà àti ẹbọ́ lè ṣe láti tún orí ẹ̀dá ṣe nìwọ̀nyí
a.) Ọmọ tí ó bá ṣí apá, ni ìyá á gbé. Èyí fi hàn pé a gbọdọ̀ gbìyànjú.
b.) Ọlọ́run n bẹ ní í ṣe ikú pa agílítí, Ọlọ́run kò kọ ìyànjú ní í gbà wọ́n sílẹ̀. Èyí ni pé bí a kò bá gbìyànjú, bí a tilẹ̀ yan orí rere, ó lè má dára tó fún ni, tàbí ki orí ire di orí burúkú mọ́ wa lọ́wọ́.
d.) Kí ojú má à rí ibi, gbogbo ara loògun ẹ̀
Abímbọ́lá (2006: xii-xiv) náà ṣàlàyé pé àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé yíyàn ni a máa ń yan orí láti òde ọ̀rún wá; Ọ̀dọ̀ Àjàlá ni a sì ti yan orí-inú. Orí-inú yií ló dúró fún àyànmọ́ tàbí ìpín àwa ẹ̀dá. Ẹni tó bá yan orí rere lọ́dọ̀ Àjàlá ní láti ṣorí rere láyé, odù ogbègúnda ló pìtàn bí èèyàn ṣeé yan orí lọ́run ọwọ́ ara oníkálúkù ní í fi í gbé orí tó bá wù ú. Ẹni tó bá yan orí rere nílé Àjàlá bó bá délé ayé tán ó di kí ó máa rí ṣe ṣùgbọn ẹni tí ó bá yanrí burúkú, bó ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ kò le è rérè kànkan jẹ. Ìrètí kan tó wà fún irú èèyàn bẹẹ ni kí o máa rúbọ kíkan kíkan.
Abímbọ́lá jẹ́ kó yé wa pé, kò sí ẹni tó le sọ irú orí tí òun yàn lọ́run, bí rere ni tàbi búburú. Onímọ̀ yìí tún tọ́ka sí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó lé jẹ́ kí orí-inú so èso rere, ó ní, a níláti rántí pé àti ẹni tó yanrí rere àti ẹni tó yanrí burúkú, gbogbo wọn ló níláti fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ṣiṣẹ́ kí wọn ó tó ó doníre. Nítorí náà orí rere tí olúwárẹ̀ yàn ó wà níbẹ̀ lásán ni, kò níí so èso rere bí ènìyàn kò bá fí ọwọ́ àti ẹsẹ rẹ̀ ṣiṣẹ́.
Ohun mìíràn tí onímọ̀ yìí mẹ́nu bà ni Ọ̀rẹ́ (Àyà) gẹ́gẹ́ bí àwọn bàbá wa ti máa ń sọ pé: ọ̀rẹ́ ẹni ní í bá ní pilẹ̀ ọrọ̀, Ará ilé ẹni ní í báni ná an. Ó ní èèyàn nílò ọ̀rẹ́ tí ó ma a bá olúwarẹ̀ gbìmọ̀ràn nípa ìgbésí ayé e rẹ̀, ọ̀rẹ́ yìí náà ni ó máa bá olúwarẹ̀ pète pèrò nípa ọjọ́ iwájú. Ó sàlàyé síwájú pé bí èèyàn yan orí rere jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí kò bá yan ọ̀rẹ́ rere, ìmọ̀ràn kò níí gún.
Adeoye (2014:11) ní ohun pàtàkì tí Yorùbá gbàgbọ́ ni pé. Àkúnlẹ́yàn ẹ̀dá ni àdáyébá wọ́n èyí ni wọ́n sì fi máa ń pa á lówe pé, Àkúnlẹyàn ni àdáyébá, akúnlẹ̀ a yàn tán, a dé ayé tán ojú ń yán ni, ìṣẹbọ, ìṣoògùn bí a ti wáyé wá rí òun ni à á rí, ó jẹ́ ìgbàgbọ́ àwọn baba wa pé gbogbo ẹdá ni ó ti bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ dá àńyàn kí wọ́n tó wá si ilé ayé. A sì lè rí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọ̀nyí nínú ìgbésí ayé “Ẹlà” ẹni tí àwọn Kìrìsítẹ́ẹ́nì mọ̀ sí “Jesu” tí gbogbo ènìyàn mọ̀ pé lọ́run ni ó ti yan iṣẹ́ àti ìgbésí ayé tí yóò lò lórí ìlé ayé (kí ó tó wá ṣe iṣẹ́ Aláàánú, olùkọ́ àti olùgbàlà aráyé).
Gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá tó sọ pé “Ẹni tí kò gba kádàrá, á gba kodoro”. Ifálérè (2014:34-36) jẹ́ kí á mọ̀ pé, ẹ̀kọ́ tí ògúndá méjì ń kọ́ wa ni pé, ìwọ̀n ni kí à lépa ajé mọ. Ó ní, ìwọ tí ó lọ sí Èkó ní ẹ̀mẹ́ta ní àlọbọ̀ lójúmọ́ àti Ìbàdàn, tí ó bá yíwọ́ kò mà sí ẹ́sún lẹ́yìn àpò o. Ọ̀run ni yóò gbà ọ́ ní ìtẹ́ a jẹ́ pé ajé lé ọ pa nìyẹn.
1.7 Àgbálọgbábọ̀
Ní orí kín-ín-ní àpilẹ̀kọ yìí, a gbìyànjú láti ṣe àfihàn fíìmù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kan nínú lítírésọ̀. A sọ èrèdí iṣẹ́ yìí. A ṣe àfihàn àwọn ọgbọ́n ìwádìí tí a ṣàmúlò, a ṣàfihàn ibi tí iṣẹ́ yóò fẹjú dé, a tọ́ka sí àwọn ìṣòro tí a bá pàdé nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí. A ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àt̀ẹyìnwá bákan náà ni a ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Orí-Inú.

PLEASE,
print the following instructions and information if you will like to order/buy
our complete written material(s).
HOW TO RECEIVE PROJECT MATERIAL(S)
After paying the appropriate amount (#3000) into our bank Account
below, send the following information to our Whatsapp 08061135915 OR bavicola13@gmail.com, edupedia17@gmail.com :
(1) Your project
topics
(2) Email
Address
(3) Payment
Name
(4) Teller Number
We will send the DOWNLOAD LINK for your material(s) immediately we
receive bank alert
BANK ACCOUNTS
Account
Name: Bakare Victor Oladapo
Access Bank 0759882072
First Bank 3077844205
Skye Bank 3023641985
GT Bank 0262146570
Access Bank 0759882072
First Bank 3077844205
Skye Bank 3023641985
GT Bank 0262146570
HOW TO IDENTIFY SCAM/FRAUD
As
a result of fraud in Nigeria, people don’t believe there are good online
businesses in Nigeria.
But
on this site, we have provided “chapter one” of all our project topics and
materials in order to convince you that we have the complete materials.
Secondly,
we have provided our Bank Account on this site. Our Bank Account contains
all information about the owner of this website. For your own security,
all payment should be made in the bank.
No
Fraudulent company uses Bank Account as a means of payment, because Bank
Account contains the overall information of the owner.
CAUTION/WARNING
Please, DO NOT COPY any of our materials on this website
WORD-TO-WORD. These materials are to assist, direct you during your
project. Study the materials carefully and use the information in
them to develop your own new copy. Copying these materials word-to-word is
CHEATING/ ILLEGAL because it affects Educational standard, and we will not be
held responsible for it. If you must copy word-to-word please do not order/buy.
That you ordered this material shows you have agreed not to copy
word-to-word.
Comments
Post a Comment